CCC HYMN 406 (Jehovah Jesu Kristi) Lyrics
- Genre:Gospel
- Year of Release:2022
Lyrics
CCC HYMN 406 (Jehovah Jesu Kristi) - IdeBBo The Serentainer
...
Jehovah, Jesu Kristi,
Michael mimo, Oga ogun,
Ijo Mimo mbe niwaju Re,
Teru tedun okan wa,
Lati saferi Emi Mimo,
E wa Ogo Orun,
Ibukun ati gbega,
Ma se fi du wa.
2. Ma bi si, si ma re si,
Ileri Re f’Abraham,
Niwoyi odun titun,
Iwo yio f’Omo se re,
Ileri yi fun Sarah,
Jo muse f’awon agan,
Ti nwon nwoju Re Baba,
F’omo b’Isaki.
3. Ninu okun pupa ni,
Farao at’ogun re,
Parun laigberi mo,
Fun isimi okan Israel,
Nigbati ‘reti dopin,
Okun diyangbe ile,
Nipa agbara iyanu yi,
Sin wa de ‘nu iye.
4. Ogbon, Imo, Oye Re,
Gegebi ti Solomon,
Igbega ati Igbala,
Bi ti Josefu, Danieli,
Imisi a ‘tohun Orun,
Bi ti Paul, Samueli,
Elmorijah Olubukun,
Se nwon ni ti ‘wa.
5. Awa nse ireti Re,
Gege b’omo ileri,
Ajo jumo jogun iye,
Ainipekun, ‘joba Orun,
Wa f’Emi orun s’atoko,
Di wa l’amure agbara,
Ka sise lai l'abawon,
Si iye ainipekun.