Ko Sogbon To Le Da Lyrics
- Genre:Juju
- Year of Release:1973
Lyrics
Instrumentals
Ko sogbon to le da
Ko si wa to le wu
Ko sona to le mo
To le fi daiye lorun o
Ko sogbon to le da
Ko si wa to le wu
Ko sona to le mo
To le fi daiye lorun o
Instrumentals
L’ojo ta ma bimo titun sile aiye
Tonile t’alejo
Lo ma ki ni kuewu
L’ojo ta ma bimo titun sile aiye
Tonile t’alejo
Lo ma ki ni kuewu
Ota omode
Bere lati ibi iragoro
Ka dani lounje nu
Oti bere ota nini
Ka dani lominu
Oti bere ota nini
Oti bo sowo aiye
Instrumentals
T’omo na ba ti
Bere sin rin
T’oba legbe
Ti won jo se ere
L’arin adugbo
Ti obi e ba le
Ra keke fun
Oti bo sowo aiye
T’oba ni ko gbe wa
Kan jo fi s’ere
Toba ni rara
Oti dota won
Oti bo sowo aiye
Won ni
Ma gbe keke e lo
A o ba e sere mo
T’ojo ba gori ojo
T’omo na ba dagba
To bere si ni
Re ile iwe
To foju si eko re
Ton se dede
Ti won ba se idanwo
Toba se ipo kini
O ti dota onipo kefa
Won fu loruko
Won l’omo teacher ni
Instrumentals
Aseyin wa aseyin bo
Omo ojo si bere ise
Oga ile ise
Ni ko ma de bise
L’agogo mejo
On se dede
On de bise lakoko
Kin ba ibise je
Awon ole afajo
Wa fun loruko
Won l’omo manager ni
Oti bo sowo aiye
Omo ton sise dede
Oye ko lasiko igbadun
Igba ti ofi jaiye
T’oba lo si party
Nibi ti won je igbadun
Toba ni kilon mu
Toba ni cocacola
Wa ni ko maiye je
Jedi jedi lo ma pa
T’oba lo si party
Nibi ti won je igbadun
Toba ni kilon mu
Toba ni cocacola
Wa ni ko maiye je
Jedi jedi lo ma pa
Toba tu je
Oga oni faaji
Ton jaiye dede
Champagne pelu schnapp
To fin yanu
Hienekens beer
Stalagards top beer
Vexbeer pelu guiness
Gbogbo e loba lara mu
Awon eda adamo
Won fun loruko
Otin l’alakorin
Fowo e mu
Instrumentals
Toba tun wa l’oje
Agba man
To loso asiko
Toju lobirin
Won fun loruko
Igberaga ti poju
Ko mo jobinrin lo
Sina l’alakorin fowo e se
Toba tun je onisuru
To kawe to gboye repete
To dogbon jaiye
Ti ki sapo
Ti ko feran obinrin
Awon eda adamo
Won fun loruko
Alakorin akada se lo woju koin koin
Instrumentals
O mu mi ranti
Itan baba kan
Pelu omo re
Ti won si ketekete
O mu mi ranti
Itan baba kan
Pelu omo re
Ti won si ketekete
Eshin pelu ketekete
O dabi moto
Ti won gun lo sode
Eshin pelu ketekete
Laiye ojo yen
O dabi moto
Ti won gun lo sode
Ketekete ti dagba
Baba pe l’omo e
Won ba mura ode
Won fe rin irin ajo kan
Gege bi agbalagba
Baba gun ketekete
Omo re tele lo
Bi won se rin siwaju die
Won pade adamo
Eda omo araye
Omo araye ni awu
Baba agbalagba
Omo re rin nile
Iwo gun ketekete
Baba ba bosile lori ketekete
Oba gbomo re sori ketekete
Won ba mu irin ajo won po
Won lo won lo won lo
Bi won se rin siwaju die
Won tu pade adamo
Eda omo araye
Omo araye tun ni awu
Baba omugo orin nile
Omo gun ketekete
Baba ba tun stray
Ogbomo sile
Osare gun ketekete
Otun gbomo sori ketekete
Eni mejimeji lori ketekete
Won mu rin ajo won po
Won lo won lo
Botun se rin siwaju die
Won pade adamo
Eda omo araye
Omo araye tun ni awu
Omo ti baba
Alailanu ni yin
Eyin mejeji lori ketekete
E fe pa ketekete ni
Baba ba woke titi
Oni ma teyin lorun
Eyin eda omo araye
Baba ba gbomo sile lori ketekete
Oun na bosile lori ketekete
Ketekete lo lofo
Baba pe lomo e
Won fese rin tele
Bi won tun se rin si waju die
Won pade adamo
Eda omo araye
Omo araye tun ni awu
Eyin mejeji eru aye niyin
Erin nile ketekete lolofo
Baba pe lomo re
Gege bi mo ti wi
Won bosile
Ketekete lo ni waju
Won fese rin tele
Won ri si waju die
Won pade adamo
Eda omo araye
Omo araye tun ni awu
Eyin mejeji eru aye niyin
Erin nile ketekete lolofo
Baba bo boju oke
Ofe ranti orin chief commander
Oni edakun efeyi kogbon
Kosogbon tele da
Kosiwa tele wu
Kosona tele mo tele fi daiye lorun o
Kosogbon tele da
Kosiwa tele wu
Kosona tele mo
Tele fi daiye lorun o
Kosogbon tele da
Kosiwa tele wu
Kosona tele mo
Tele fi daiye lorun o
Kosogbon tele da
Kosiwa tele wu
Kosona tele mo
Tele fi daiye lorun o
Ile aiye
Fun gbadi eni o
Omo araye esere o
Ile aiye
Fun gbadi eni o
Omo araye esere o
Africa wuwa rere
Rere lo pe
Omo araye esere o
Ile aiye
Fun gbadi eni o
Omo araye esere o
Commander Ebenezer
Do your best and leave the rest
Commander Ebenezer
Do your best and leave the rest
Ile aiye
Fun gbadi eni o
Omo araye esere o
Ile aiye
Fun gbadi eni o
Omo araye esere o
Rere lo pe
Africa ma wuwa rere
Omo araye esere o
Ile aiye
Fun gbadi eni o
Omo araye esere o